Ìwà Àjẹbánu
Ìrísí
Ìwà Àjẹbánu jẹ́ abala ìwà àìṣòdodo tàbí ìwà ọ̀daràn tí àwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́, àwọn òṣèlú tó wà nípò àṣẹ tàbí agbára máa ń hù fún àǹfàní ara wọn. Ó jẹ́ ìwà ìṣagbáralò fún àǹfàní ara ẹni. Lára àwọn ìwà Àjẹbánu ni Ẹ̀gúnjẹ gbígbà, ìwà ìkówójẹ nípò àṣẹ, ìṣègbè fún ẹ̀bí, ará tàbí ọ̀rẹ́ ẹni fún àǹfàní láìtẹ̀lé ìlànà tàbí òfin.[1] Ìwà Àjẹbánu máa ń ṣẹlẹ̀ ní orísirísi ìwọ̀n. Ó lè wáyé níbi ìṣe kéréje [2] ṣùgbọ́n èyí tí ó bá wáyé láàárín àwọn olóṣèlú tàbí àwọn tó wà nípò àṣẹ jẹ́ èyí tí ó gbajúmọ̀ jùlọ. Bí ó tilẹ̀ wù kí ó kéré tó, ohun tí kò dára, kò lórúkọ méjì.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Report" (PDF). siteresources.worldbank.org. Archived from the original (PDF) on 5 May 2015. Retrieved 25 September 2012.
- ↑ Elliott, Kimberly Ann (1950). "Corruption as an international policy problem: overview and recommendations". Washington, DC: Institute for International Economics. https://piie.com/publications/chapters_preview/12/10ie2334.pdf.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |