Jump to content

Augustus Aikhomu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdàkọ:Use Nigerian English Àdàkọ:Refimprove


Augustus Aikhomu
8th Vice President & Chief of General Staff
In office
October 1986 – August 1993
ÀàrẹIbrahim Babangida as Military President of Nigeria
AsíwájúEbitu Ukiwe
Arọ́pòOladipo Diya
Chief of Naval Staff
In office
January 1984 – October 1986
AsíwájúAkintunde Aduwo
Arọ́pòPatrick Koshoni
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí20 October 1939
Aláìsí17 August 2011(2011-08-17) (ọmọ ọdún 71)
(Àwọn) olólùfẹ́Rebecca Aikhomu
Alma materYaba College of Technology
Britannia Royal Naval College
NIPSS
Military service
Allegiance Nigeria
Branch/service Nigerian Navy
Years of service1958–1993
Rank Admiral

Ọ̀gágun Augustus Akhabue Aikhomu tí wọ́n bí lógúnjọ́ oṣù kẹwàá ọdún 1939,ti o sìn papòdà lọ́jọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹjọ ọdún 2011 jẹ́ Ọ̀gágun orí omi, olóyè Admiral tí orílẹ̀ èdè Nigeria, tí ó sìn jẹ́ Igbákejì Ààrẹ Ológun orílẹ̀-èdè Nigeria lábẹ́ Ààrẹ Ológun, Ọ̀gágun-yányán, General Ibrahim Babangida ní ọdún 1986 sí 1993.

Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Ọ̀gágun Augustus Aikhomu ní ìlú Idumebo-Irrua, ní Ìpínlẹ̀ Ẹdó,[1]Nàìjíríà . Augustus lọ sí ilé-ìwé gíga ti Yaba College of Technology, Royal Britannia Naval College ní Dartmouth, England, Long Gunnery Specialist Course, India àti National Institute of Policy and Strategic Studies, Kuru, Nigeria.

Iṣẹ́ ológun orí omi rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Aikhomu dara pọ̀ mọ́ àwọn ológun orí omi Nigeria lọ́jọ́ kìíní oṣù Kejìlá ọdún 1958. Ó dára pọ̀ mọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ogún, Royal Navy gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́ ní HMSFisgard, lẹ́bàá Torpoint, East Cornwall ní oṣù kìíní ọdún 1959. Ó wà ní Grenville Division ní HMS Fisgard, tí ó sìn yẹ kí ó parí ìkẹ́kọ̀ọ́ oṣù mẹ́rìndínlógún, abala kìíní rẹ̀ ní ìparí oṣù kẹrin ọdún 1960.

Aikhomu jẹ́ Ọ̀gágun-àgbà, NNS Dorina, Ọ̀gágun orí omi ní olú-ilé-iṣẹ́ àwọn ológun orí omi ní ọdún 1983 sí 1984. Bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ chief of naval staff lọ́dún (1984–86).

Igbákejì Ààrẹ àti Olórí-yáyán àwọn òṣìṣẹ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀gágun jẹ Nigeria, tí ó sìn jẹ́ Igbákejì Ààrẹ-ológun Nigeria lábẹ́ Ọ̀gágun Ibrahim Babangida ní ọdún 1986 sí 1993.

Iṣẹ́ lẹ́yìn ológun

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Òun ni Alága àwọn ìgbìmọ̀ máàjẹ́-ò-bàjẹ́ tí ẹgbẹ́-òṣèlú alátakò All Nigeria Peoples Party, ní Nigeria. Aikhomu ṣe ìrànlọ́wọ́ ìwòsàn àrùn ibà-lásà, lassa fever ní ilé-ìwòsàn, Irrua Specialist Hospital.[2] Ó kú ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹjọ ọdún 2011. Aya àti ọmọ márùn-ún tí ẹbí ló gbẹ̀yìn rẹ̀.

  1. "Nigerians react as Admiral Augustus Aikhomu dies @72". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2011-08-17. Retrieved 2022-03-17. 
  2. "Nigeria Centre for Disease Control". ncdc.gov.ng. Retrieved 2020-05-28.